ODUN ARINGIYA NI ILU IKARE AKOKO GEGE BI ERE ONISE


ODUN ARINGIYA NI ILU IKARE AKOKO GEGE BI ERE ONISE
ITOKA AKOONU
Ifisori
Idupe
ORI KIN – IN – NI
Ifaara
Alaye die nipa odun ibile ni ile
Yoruba
Aigbagbo awon Yoruba nipa bibo orisa
Itan isendale ilu Ikare Akoko
Ise ati esin awon ara ilu naa
ORI KEJI
Itan isendale odun aringiya
Bi a se n se odun naa
Awon ohun elo fun odun naa
Odun Aringiya gege bii ere onise
ORI KETA
Igbagbo awon ara ilu nipa sise odun
naa
Ipa ti oba maa n ko ninu odun naa
Ipa ti awon ara ilu maa n ko ninu
odun naa
ORI KERIN
Awon eewo odun Aringiya
Ayipada ti o ti de ba odun naa
Ero wa nipa odun naa
ORI KARUN – UN
Asokagba
Awon oro ti o ta koko
Awon ti a fi oro wa lenu wo
Awon iwe itokasiORI KIN – IN – NI
IFAARA
          Ile
aye n yi lo a n to irorun, itura ati iberu Eledaa ni awon omo ode oni ti ju
sonu sinu ogbun.  Won ti gbagbe gbogbo
asa baba n la won.
          Idi
ti a fi yan akori ise yii laayo ni wi pe gbogbo orisa ti awon baba n la wa bo
ni aye atijo ni a fe ki awon eniyan mo wipe o ni idi Pataki ti won fi n bo, bii
kii o maa mu irorun wo ilu, tabi ki alaafia maa joba ni ilu ati pe ohun idunu
ni o je fun wa lati ko iwe apinleko yii fun iwulo ojo iwaju nitori pe awon
Yoruba ni igbagbo ti o jinle nipa bibo orisa tabi ki won maa se odun kan
jakejado orile ede kaaaro – oojiire.
          Ko
si ise kan pato
lori akori yii yato si itan ti a gbo lenu awon agbalagba ati ohun ti a ri nigba
ti won ba n se odun naa.
Iwe apileko yii dale itan ilu Ikare
Akoko, ipo Owa Ale ati Olukare, itan isedale odun Aringiya, igba ti won n se
odun naa bi won se n mura sile fun un, bi won se n se odun naa ati ohun elo
odun naa tun jeyo.
Ipa ti oba n ko ninu odun yii ati
igbagbo awon ara ilu nipa sise odun naa, pelu Pataki odun Aringiya gege bii ere
onise ni apileko yii tun kiyesi.
Iwe apileko yii se agbeyewo awon eewo
odun Aringiya, ayipada ti o ti deba odun naa, ero wa ni pato ati siso itumo
awon oro ti o takoko ati iwe itokasi ni o waye leyin ninu ise yii.
Ona ti a gba lati sise yii ni lati so
awon itan ti a ti maa n gbo lenu awon agbalagba ati pe a se akojopo ohun ti a
ri lasiko ti won ba n se odun yii.
Eyi fun wa ni aaye lati ni imo to
jinle nipa sise odun naa, a si ni igbagbo wipe akitiyan wa lori ise yii yoo mu
ilosiwaju ba odun yii.
Ise yii yoo si tun je ona kan Pataki lati polongo asa odun ibile wa kaakiri orile ede Naijiria.
ALAYE DIE NIPA ODUN IBILE NI ILE
YORUBA
Se ko kuku si bi ti a kii gbe dana
ale, jakejado ile Yoruba ni odun ibile ti se Pataki, idi niyi ti o fi je wipe
awon esin ati ohun ti baba n la wa n bo ko ni iye.
Igbagbo awa Yoruba ni wipe Olorun kan soso ni o wa ati pe
Olorun naa si tobi ju gbogbo awon orisa ibile ti o ku lo, Olorun yii ni Yoruba
pe ni Olodumare ti won gba pe o n lo n sakoso aye ati orun.
Okanojokan onimo isaaju bii Olu
Daramola (1975), Adebayo Jeje (1970) Ogunbowale P.O (1974) ni won ti salaye
daaye kan
nipa odun ibile Yoruba.
Alaaye ti a kan fe se nibi, ko ju
lati kin ero won leyin, loju awon onimo yii won gba pe baba ni Olodumare je si
gbogbo awon orisa ibile ti o ku, awon orisa wonyii ni iko ti a maa n ran si
Olodumare, orisirisi ni awon orisa wonyii.
Awon kan duro gege bi oguna gbongbo ti o je wipe
orun ni won ti wa si Aye iru won bee ni Obatala, Orunmila, Esu, Ogun ati beebee
lo.
OBATALA: Itan
so fun wa wipe Obatala ni Olodumare koko da ninu gbogbo orisa ati wipe
Olodumare fun ni agbara lati maa ran ohun lowo nipa sise oju imu enu ati gbogbo
awon eya ara ti o ku leyin ti Olodumare ba ti mo ara ni borogidi tan idi ni eyi
ti a fi maa pee ni igbakeji Olodumare, ohun ni o maa je ki a maa kii bayii pe.
                             Obatala
oninu funfun
                             Eni
soju semu Orisa ni
                             Maa
sin o ……………
Siwaju si a kole menu ba gbogbo orisa
ti o ku ti o si ti di orisa akunlebo.
Itan si tun so fun w ape awon
alagbara kan wa ti won ti n gbe ile aye yii rii sugbon ti won ti di orisa leyin
iku won ti won n bo gege bi orisa lati fi emi imoore ati idunu won han si won
ni iranti oore ti won ti se nigba aye won. 
Iru awon orisi wonyii ni oke – Ibadan ni
ilu Ibadan,
Olosunta ni ilu Ikere – Ekiti, Agolomologo ni odo Ikare Akoko ati ni Idanre naa
won maa n bo Orosun fun abo ti o peye ni igba ogun.
Looto, gbogbo ile Yoruba ni a ti n se
odun ogun sibe o se Pataki o si tun gbile jule ninu awon odun ibile ni ilu Ire
– Ekiti, Ado –
Ekiti, Ondo ati Ilesa.
A ko si ni saifi enu ba odun egungun
nitoripe gbogbo ile Yoruba ni a ti n see, igbagbo won si ni wipe awon baba n la
wa ti o ti ku ni o pada waye ninu ago to won si fe dara po mo wa lati le se
ibeere fun awon ohun ti a ba fe lowo won.
Lakootan awon odun wonyii ni o ni
aworo Pataki ise won aworo si ni lati se agbateru ni ojo odun naa, oba ni o si
maa n je olori awon Aworo odun ibile ni ile Yoruba.
AIGBAGBO AWON YORUBA NIPA BIBO AWON
ORISA WONYII
Igbagbo awon Yoruba nipa bibo awon
orisa wonyii ni wipe ti won ba ti boa won orisa naa, gbogbo ire odun naa, yoo
je tiwon, Aboyun ile a bi were, Agan ti ko bi a towo ala bosun ati wipe ibikibi
ko ni wo ile to won wa.  Won sit un ni
igbagbo wipe odun kan
ti won ba fi awon orisa wonyii sile laibo odun naa ko ni dun fun won.  Ile koni roju oko ko ni raye, orisirisi ajalu
ni o maa de si ara ilu nitori pea won orisa wonyii le bi nu si won, ti orisa ba
si binu ayafi ti won ba bi Ifa leere ohun ti won yoo fi petu si okan orisa bee
lati da isele ibi duro laarin ilu.  Idi
ni eyi ti awon Yoruba fi ni igbagbo ti o muna doko lori awon orisa ibile won
gbogbo.
ITAN ISEDALE ILU IKARE AKOKO
Opo itan ni a gbo wipe o room Yoruba
ti se tedo si ile Ife
di oni olooni, bee naa ni itan ilu Ikare se pin si ona meji.
Itan ti a gbo lati enu Kabiyesi Owa
Ale ti ilu Ikare Akoko ni ojo keta osu karun – un odun 2008, so pe Agbaode ni
oruko eni to koko te ilu Ikare do o si je okan lara awon omo Oduduwa, Agbaode,
kuro ni Ife pelu ebii re ati opolopo eniyan ni Adugbo Eruwa, O kuro ni Ife
nitori pe o yan Ade siwaju awon egbon ore, Agbaode ni o je Oba siwaju awon
egbon re ni won se n pe ni Owa ti o le ti o tumo si OWA ALE, Owa ni ile Yoruba
duro gege bii Oba, apeere ni Owa abokun, owa agbajo.
Ni eyin igba ti o ti rin kaakiri fun
opo odun.  O dowo ni ibi apa oke n la kan
ti a n pe ni oke Ikare ki o to di wipe o rewale asa, o ni oloye mejila bii Oniku,
Olokoja, Onigbede, Aro, Olowa Balogun, Elemeje, Elekan, Onisakunle, Olokepaye,
Eleketun, leyin eyi awon Owa Ale miran ti o tun je ni Rotoye, Olarun Ademoye,
Diromoye Agbole, Amugbirigidi, Ameyinpa, Orukusuku, Adetiba, Ojugbo Gbogi,
Owajimite iranja Ajiboye, Adegbite ati Kolapo Adedoyin ti o wa lori ite bayii.
Itan ti a gbo lati enu ogbeni Jimoh
Ologun ni adugbo okoja ni ojo kerinlelogun osu karun – un ni odun 2008 bakanna
so fun wa pe lati ilu Ife ni Ikare ti yapa wa ti won si tedo si ibi ti won wa di
oni oloni.  Ajagunna ti o je okan lara
awon omo oduduwa ni o kuro ni ile Ife
pelu opo eniyan.  Ibi ti won ti kuro Ife ni adugbo Ilare ti won
si tedo si isale Ikare di oni oloni.
Leyin ti Olukare akoko eyi ti o n je
Ajagunna yii roke alo waon Olukare miran ti o tun je ni Amusa Momoh, Hasan
Babatunde, Ajogunna, Olonoola Elegbe Ketimigbo Ata alila Arokerese Oba Momoh
Adu ati bee bee lo pelu Momoh Akadiri Saliu ti o wa lori oye bayii.
Awon ijoye Olukare ni oloye sasere
olododo orisakumen, elekan, olokeruwa, obanla, omotosho Yeyemeso Iyaalaye
Olodalyare Onigbede Balogun.
IPO OWA ALE ATI OLU IKARE
Awon wonyii ni o duro gege bii
asiwaju fun awon eniyan ilu ikare Akoko, ni o maa n se odun ojo ikare, odun ojo
ikare, odun Agolomolodo, imole okela o si tun je  oba olori elesin musulumi.
Owa Ale ni o maa se odun Aringiya,
ijeroba, odun ijesu ti a mo si igbodo, gidigbe ijawene omolokoja Aoyo ati bee
bee lo.
ISE ATI ESIN AWON ARA ILU NAA
Ise agbe ati ise onisowo ni ise,
Pataki julo ti awon ara ilu ikare n se, won mo nipa ogbin koko , won tun maa n
gbin isu koko , agbado ati nnkan ewe leyin eyi opolopo ise ni won sit un se
gege bii ise aso hihun , Aro mimu, ise Agbede ati owo sise, awon omowe onise
ijoba naa ko si lo un ka.
ESIN
Ni Aye atijo orisirisi orisa ni awon
ara ilu yii n bo ki awon esin igbalode to daye lara awon orisa wonyii ni ifa,
urere, osanyin, oya, Atan, Gayingayin ati bee bee lo . ko si eyi ti won fi owo
yepere mu ninu awon orisa wonyii, karakara ni won si n se odun awon orisa naa
ni sise-n-tele sugbon ni igba ti esin igbalode , imale ati igbagbo de, n se ni
awon ara ilu lokunrin ati lobinrin tewo gba esin naa, eyi si mu ki esin ibile
bere si kase nile titi di oni yii.
ITOSE ORO
1.                
Itan
ti o romo owa Ale
2.                
Itan
ti o romo olukare.
ORISUN IMO
1.                
Lati
enu kabiyesi owa Ale ti ilu ikare- Akoko
2.                
Lati
enu jimoh ologun ni Adgbo okoja ni ilu ikare- Akoko.
          Iwadii
yii waye ni ojo keta osu karun-un odun 2008.online payment nigeria HOW TO ORDER FOR COMPLETE PROJECT MATERIAL

STEP 1

Complete Project Price: ₦3,000 (We accept mobile tranfer)

» Bank Branch Deposits, ATM/online transfers (Amount: ₦3,000 NGN)

Bank: FIRST BANK Account Name: OMOOGUN TAIYE Account Number: 3116913871 Account Type: SAVINGS Amount: ₦3,000 AFTER PAYMENT, TEXT YOUR TOPIC AND VALID EMAIL ADDRESS TO 07064961036 OR 08068355992 OR Click Here

Bank: ACCESS BANK Account Name: OMOOGUN TAIYE Account Number: 0766765735 Account Type: SAVINGS Amount: ₦3,000 AFTER PAYMENT, TEXT YOUR TOPIC AND VALID EMAIL ADDRESS TO 07064961036 OR 08068355992 Click Here

Bank: HERITAGE BANK Account Name: OMOOGUN TAIYE Account Number: 1909068248 Account Type: SAVINGS Amount: ₦3,000 AFTER PAYMENT, TEXT YOUR TOPIC AND VALID EMAIL ADDRESS TO 07064961036 OR 08068355992 Click Here

STEP 2.

Send Your Details and Project topic To us by filling this form.